Friday, July 12, 2019

         Irọ



 Irọ níi tiwọn sọgbun ayé

Òun yi náà níí ti wọn sí kòtò

Irọ ní rọ ni lóyè

Irọlabi ọjọ òun àná nkọ?
Irọ ti rọ lọ
Irọlabi dẹni irọ lóyè
Irọlabi dẹni ìgbàgbe.


Irọ o ni salai gbasọ ìyí lára ọmọlabi
Ko ní salai gbà bata àpónlé lẹsẹẹ rẹ
Ìwọ ọmọ ìyá mi o
Bóo ba bawọn rírọ́ 
Fi gbogbo ara yan-an lódì
Àbó tilẹ̀ fẹ́ bá ẹ dá ọwẹkẹ
Jọwọ koo loju mọlẹ 
Mofẹ koo mọ wipe
Aṣọ tírọ́ ba wọ fún ni ni kọrọ
Àárín ọjà ni yóò ti gba a.


Njẹ ọba lóún pa irọ ní
Àbí ìjòyè lo mu ni korikosun
Bó ba iwá se oloselu ọwẹwẹ
Àbó tilẹ̀ wá jẹ ọgá ilé-isẹ́
Irú àwọn wọ̀nyí
Wọn kìí níyì ní apọnle
Wọn a dẹni yẹyẹ láwùjọ ayẹyẹ.

Tẹti ẹ, gbọ mi ọrẹ,

Mọpe ọjà irọ toun ta waiwai 
Pánsá tabi panda ni 
Ofuutu fẹẹtẹ
Ọjà wasa.

Ìwọ ọmọ ìyá mi o 

Ẹgbọn, burọda ati aburo
Jọwọ
Máṣe bawọn raja irọ
Masise bawọn tàá
Koo maa baa kabamọ.
  
   (C) Olasunkanmi Sodiq S'Ola.
Àkíyèsí: Awọn ami ori ewi yii ko pe nitori idiwọ ránpẹ́. Ọmọ Yorùbá atata ẹ bámi fi ìfẹ́ kàá.

x

No comments:

Post a Comment

   POETS Teachers of all teachers Who teach the whole world By dipping their pens To the innermost bottom of all hearts Teachers of all...